Nipa Saison Africa2020
Àbá ìṣàkóso ohun ìṣẹ̀ǹbáyé dá lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó ní àtò àgbékalẹ̀ ṣókí ajẹmáwòrán ilé gẹ́gẹ́ bí ti agbègbe àti sàkání agbára. Lẹ́yìn tí a bá ti ṣe àgbékalẹ̀ ṣókí náà nípa àǹfààní ìkọ̀kọ̀/bòńkẹ́lẹ́, tí a sì sọ wọ́n di ohun èlò ìṣẹ̀dá tó níye, tí ó ń ṣe àmúró àtò àìdọ́gba, nípa ìlàkàkà láti mú kí ìṣe ẹ̀ka-ìmọ̀ náà parẹ́ pátápátá.
Ní ìlànà ìṣàkóso ohun ìṣẹ̀ǹbáyé, àwọn alájọmójútó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ti ilẹ̀ Áfíríkà mẹ́rin dá àbá àgbékalẹ̀ ṣókí tiwọn láàrín àgbékalẹ̀ ṣókí ti Saison Africa2020. Gẹ́gẹ́ bí èrò ti àjọ ètò owó pàṣípààrọ̀, wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ pẹpẹ kan lórí ẹ̀rọ ayélujára gẹ́gẹ́ bí agbo ìmọ̀ àti ìṣèdá tó níye nípasẹ̀ àwọn alábápàdé tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn pàṣípààrọ̀. Ọ̀wọ́ àwọn òfin kan tí àgbékalẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìpè-àti-ìfèsì ń pe àwọn ajẹ́jọ́ ní ṣísẹ̀ntẹ̀lẹ́ láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kí wọ́n sì jùmọ̀ ṣe àtò àgbékalẹ̀ ṣókí ti ajẹmáwòrán ilé ní ìmọ̀ tàbí àkóónú ìpèsè òfin ìjọba nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àmúlò oríṣiríṣi ìwọ̀n àti àwọn ọ̀nà ìní, àmúṣe àti ìṣojú.
Àwọn ajẹ́jọ́ jẹ́ àwọn obìnrin ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà aṣàtìpódọmọonílẹ̀ àti aláròjinlẹ̀ ẹ̀dá; ìtàn ìlànà ìkànìyàn àtìgbàdégbà tí a yọ kúrò nínú àmúlò ìṣẹ̀dá ìmọ̀ ṣùgbọ́n tí ìlànà àmúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìrísí àti ìhùwàsí ti àdáṣe ayé/iṣẹ́ àgbàríjọṣe.
ÌṢÍNINÍYÈ
“Àwọn àlá tí kò lè ṣẹ, èyí tí kò fi ohun tí a jẹ́ hàn, bí kò ṣe àfihan èrò ọkàn àwọn aláwọ̀ funfun lásán. Wọ́n jẹ́ abala ìmọ̀ ara ẹni àwọn aláwọ̀ funfun tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ èyí tí wọ́n wá ṣe àtúnfihàn sí wa, bí ẹni pé wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí a le fi ògún rẹ̀ gbárí àti ìrísí tí kò lábàwọ́n nípa ara wa. Àmọ́ sáá o, wọn kì í ṣẹ ohun tí ó jẹ wá lógún.” ― Grada Kilomba
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ àti akẹgbẹ́ (wa),
Nígbà tí a bá ní láti ṣe ògbufọ̀ fún àtò àgbékalẹ̀ ṣókí ti ajẹmáwòrán ilé ti Saison Africa2020, saay/yaas ní ìsípayá nípa ìlànà tí ó mọ rírì ọ̀nà ìṣàlàyé, ìfaradà àti àkoónú àtọwọ́ọ́dá àwọn Áfíríkà àti aṣàtìpódọmọonílẹ̀, nípa pípèsè àtakò tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sí èrò òdì tó dá yàtọ̀ nípa Áfíríkà ní ṣíńsẹ̀tẹ̀lé “...láti ṣàlàyé fún àwọn tí ó ní àǹfàní láti má ní òye” saay/yaas ṣe àtò àfihàn “sàn-án” láti jẹ́ abala/apá ìrísí ìfihàn tó wà lójú kan pẹ̀lú gbèdéke àti díndín àtakò. Ní ìfèsì, a ṣe ìdásílẹ̀ ìtàkùn ònídíjítà níbí.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-apọ́nlé tí ṣe le “pọ́n tàbí yán ọ̀rọ̀-àpèjúwe”, “ṣísàlàyé ìbáṣepọ̀ ibi, àkókò, sábàbí, ibá, ìdí, ìpele, abbl.”, ìlò ọ̀rọ̀ yìí nínú àkọ́lé níbí, ṣe é kà gẹ́gẹ́ bí òun, níbí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè yà bàrà sí àwọn ìbáṣepọ̀ tó ta kókó ní ìgbà àti àkókò tí ó wà nínú kíkọ́ àṣà ìyàwòrán ilé gẹ́gẹ́ bí obìnrin àti ọmọ Áfíríkà/aṣàtìpódọmọonílẹ̀ ní àwùjọ tí ó jẹ́ kìkì ọkùnrin aláwọ̀ funfun ni ó ní àǹfàní ètò ọrọ̀ ajé àti àtò ìkóra-ẹni níjánu ní ẹ̀ka ìyàwòrán ilé tí ó gùnlé ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àgbáyé.
Èyí jẹ́ alàyè àwọn èrò àtìgbàdégbà tí ó máa ń yí pàdà lóòrèkóòrè, àwọn ohun àmúwọlé tí ó níye lórí, tí ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìbéèrè tí ó rọ̀ mọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òye àti àtò ṣíṣiṣẹ ayàwòrán ilé láti ìgbà wọ̀n-ọnnì wá nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ìgbà gbogbo pẹ̀lú àwọn ìbáṣepọ̀, ìrírí, ipò àti òye pàtó tí ó jẹmọ́ Áfíríkà àti àwọn aṣàtìpódọmọonílẹ̀. Ojú òpó náà ṣe àgbéyèwò bí ó ti ṣe pàtàkì láti ṣe àpéjọ ìta gbangba níbi tí ìfikùnlukùn àti àmúgbòòrò àwujọ àwọn obìnrin adúláwọ̀ níbí ó bá ṣe lè gbòòrò tó, awọn àdáṣe ayé àti ìṣe ti ohun ìní àdápinu ẹni.
A pè ọ́ láti ṣe àtọwọ́dá “ṣekárími” tìrẹ nípa ṣíṣe àgbékalẹ̀ iṣẹ́, èrò, ìtọ́kasí, inú dídùn, ìbẹ̀rù, àròjinlẹ̀, ìmọ̀ràn (àfojúrí, ohùn tàbí àkọsílẹ̀), iṣẹ́ tí a ti ṣetán tàbí èyí tí a kò tí ì ṣetán tàbí èyí tí a ń gbèrò, ìbéèrè, àlàyé tàbí àtakò èrò ẹlòmíràn tí kò ní gbèdéke tàbí àyọrísí. A lè ṣe àfihàn àwọn nkàn wọ̀nyí ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀ láìdárúkọ ẹni. O lè farahàn bí olùyàwòrán ilé, àjùmọ̀ṣe, ọlọ́wọ̀ọ́ tàbí aládàáṣe. Ẹ̀wẹ̀, nídàkejì, a pè ọ́ láti pe àwọn elòmíràn láàárín àjọ Áfíríkà/ aṣàtìpódọmọonílẹ̀ láti ṣe àgbékalẹ̀ tiwọn náà, nípa báyìí, kí wọ́n mú àwọn olóye rẹpẹtẹ àti àwọn alàdàáṣiṣẹ́ tí a le lò ní ọ̀nà tí ó gbòòrò jùlọ nínú àtò ajẹmọ-ìyàwòrán ilé àti àdáṣe ayé àti àmúṣe ti ohun ìní àdápinu ẹni wá sí àwùjọ.